Gẹn 24:2-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Abrahamu si wi fun iranṣẹ rẹ̀, agba ile rẹ̀ ti o ṣe olori ohun gbogbo ti o ni pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ọwọ rẹ si abẹ itan mi;

3. Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé:

4. Ṣugbọn iwọ o lọ si ilẹ mi, ati si ọdọ awọn ará mi, ki iwọ ki o si fẹ́ aya fun Isaaki, ọmọ mi.

5. Iranṣẹ na si wi fun u pe, Bọya obinrin na ki yio fẹ́ ba mi wá si ilẹ yi: mo ha le mu ọmọ rẹ pada lọ si ilẹ ti iwọ gbé ti wá?

6. Abrahamu si wi fun u pe, Kiyesara ki iwọ ki o má tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀.

7. OLUWA Ọlọrun ọrun, ti o mu mi lati ile baba mi wá, ati lati ilẹ ti a bi mi, ẹniti o sọ fun mi, ti o si bura fun mi, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun; on ni yio rán angeli rẹ̀ ṣaju rẹ, iwọ o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ fun ọmọ mi wá.

8. Bi obinrin na kò ba si fẹ́ tẹle ọ, njẹ nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ni ibura mi yi: ọkan ni, ki iwọ máṣe tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀.

9. Iranṣẹ na si fi ọwọ́ rẹ̀ si abẹ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, o si bura fun u nitori ọ̀ran yi.

10. Iranṣẹ na si mu ibakasiẹ mẹwa, ninu ibakasiẹ oluwa rẹ̀, o si lọ; nitori pe li ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹrù oluwa rẹ̀ wà: o si dide, o si lọ si Mesopotamia, si ilu Nahori.

11. O si mu awọn ibakasiẹ rẹ̀ kunlẹ lẹhin ode ilu na li ẹba kanga omi kan nigba aṣalẹ, li akokò igbati awọn obinrin ima jade lọ pọnmi.

12. O si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, ṣe ọ̀na mi ni rere loni, ki o si ṣe ore fun Abrahamu oluwa mi.

13. Kiyesi i, emi duro li ẹba kanga omi yi; awọn ọmọbinrin ara ilu na njade wá lati pọnmi:

14. Ki o si jẹ ki o ṣe pe, omidan ti emi o wi fun pe, Emi bẹ̀ ọ, sọ ladugbo rẹ kalẹ, ki emi ki o mu; ti on o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu: on na ni ki o jẹ ẹniti iwọ yàn fun Isaaki iranṣẹ rẹ; nipa eyi li emi o si mọ̀ pe, iwọ ti ṣe ore fun oluwa mi.

15. O si ṣe, ki on to pari ọ̀rọ isọ, kiyesi i, Rebeka jade de, ẹniti a bí fun Betueli, ọmọ Milka, aya Nahori, arakunrin Abrahamu, ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀.

16. Omidan na li ẹwà gidigidi lati wò, wundia ni, bẹ̃li ẹnikẹni kò ti imọ̀ ọ: o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o si pọn ladugbo rẹ̀ kún, o si goke.

Gẹn 24