Gẹn 22:5-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Abrahamu si wi fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, pe, Ẹnyin joko nihin pẹlu kẹtẹkẹtẹ; ati emi ati ọmọ yi yio lọ si ọhùn ni, a o si gbadura, a o si tun pada tọ̀ nyin wá.

6. Abrahamu si mu igi ẹbọ sisun na, o si dì i rù Isaaki, ọmọ rẹ̀; o si mu iná li ọwọ́ rẹ̀, ati ọbẹ; awọn mejeji si jùmọ nlọ.

7. Isaaki si sọ fun Abrahamu baba rẹ̀, o si wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi, ọmọ mi. On si wipe, Wò iná on igi; ṣugbọn nibo li ọdọ-agutan ẹbọ sisun na gbé wà?

8. Abrahamu si wipe, Ọmọ mi, Ọlọrun tikalarẹ̀ ni yio pèse ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun: bẹ̃li awọn mejeji jùmọ nlọ.

Gẹn 22