7. OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia; o si mí ẹmí ìye si ihò imu rẹ̀; enia si di alãye ọkàn.
8. OLUWA Ọlọrun si gbìn ọgbà kan niha ìla-õrùn ni Edeni; nibẹ̀ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si.
9. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun mu onirũru igi hù jade wá, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; ìgi ìye pẹlu lãrin ọgbà na, ati igi ìmọ rere ati buburu.
10. Odò kan si ti Edeni ṣàn wá lati rin ọgbà na; lati ibẹ̀ li o gbé yà, o si di ipa ori mẹrin.
11. Orukọ ekini ni Pisoni: on li eyiti o yi gbogbo ilẹ Hafila ká, nibiti wurà wà;
12. Wurà ilẹ na si dara: nibẹ ni bedeliumu (ojia) wà ati okuta oniki.
13. Orukọ odò keji si ni Gihoni: on na li eyiti o yi gbogbo ilẹ Kuṣi ká.
14. Ati orukọ odò kẹta ni Hiddekeli: on li eyiti nṣàn lọ si ìha ìla-õrùn Assiria. Ati odò kẹrin ni Euferate.