6. Abramu si là ilẹ na kọja lọ si ibi ti a npè ni Ṣekemu, si igbo More. Awọn ara Kenaani si wà ni ilẹ na ni ìgba na.
7. OLUWA si fi ara hàn fun Abramu, o si wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ̀ li o si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA ti o fi ara hàn a.
8. O si ṣí kuro nibẹ̀ lọ si ori oke kan ni ìha ìla-õrùn Beteli, o si pa agọ́ rẹ̀, Beteli ni ìwọ-õrùn ati Hai ni ìla-õrùn: o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si kepè orukọ OLUWA.
9. Abramu si nrìn lọ, o nlọ si ìha gusù sibẹ̀.
10. Ìyan kan si mu ni ilẹ na: Abramu si sọkalẹ lọ si Egipti lati ṣe atipo nibẹ̀; nitoriti ìyan na mu gidigidi ni ilẹ na.
11. O si ṣe, nigbati o kù si dẹ̀dẹ lati wọ̀ Egipti, o wi fun Sarai aya rẹ̀ pe, Kiyesi i nisisiyi, emi mọ̀ pe arẹwà obinrin lati wò ni iwọ:
12. Nitorina yio si ṣe, nigbati awọn ara Egipti yio ri ọ, nwọn o wipe, aya rẹ̀ li eyi: nwọn o si pa mi, ṣugbọn nwọn o dá ọ si.
13. Mo bẹ̀ ọ, wipe, arabinrin mi ni iwọ iṣe: ki o le irọ̀ mi lọrùn nitori rẹ; ọkàn mi yio si yè nitori rẹ.
14. O si ṣe nigbati Abramu de Egipti, awọn ara Egipti wò obinrin na pe arẹwà enia gidigidi ni.
15. Awọn ijoye Farao pẹlu ri i, nwọn si ròhin rẹ̀ niwaju Farao; a si mu obinrin na lọ si ile Farao.
16. O si nṣikẹ Abramu gidigidi nitori rẹ̀: on si li agutan, ati akọ-malu, ati akọ-kẹtẹkẹtẹ, ati iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, abo-kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ.
17. OLUWA si fi iyọnu nla yọ Farao ati awọn ara ile rẹ̀ li ẹnu, nitori Sarai aya Abramu.
18. Farao si pè Abramu, o wipe, ewo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? ẽṣe ti iwọ kò fi wi fun mi pe, aya rẹ ni iṣe?