1. OLUWA si ti wi fun Abramu pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ara rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ, si ilẹ kan ti emi o fi hàn ọ:
2. Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni iwọ o si jasi:
3. Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye.