Gẹn 11:31-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Tera si mu Abramu ọmọ rẹ̀, ati Loti, ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ati Sarai aya ọmọ rẹ̀, aya Abramu ọmọ rẹ̀; nwọn si ba wọn jade kuro ni Uri ti Kaldea, lati lọ si ilẹ Kenaani; nwọn si wá titi de Harani, nwọn si joko sibẹ̀.

32. Ọjọ́ Tera si jẹ igba ọdún o le marun: Tera si kú ni Harani.

Gẹn 11