Gal 5:23-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni.

24. Awọn ti iṣe ti Kristi Jesu ti kàn ara mọ agbelebu ti on ti ifẹ ati ifẹkufẹ rẹ̀.

25. Bi awa ba wà lãye sipa ti Ẹmí, ẹ jẹ ki a si mã rìn nipa ti Ẹmí.

26. Ẹ máṣe jẹ ki a mã ṣogo-asan, ki a má mu ọmọnikeji wa binu, ki a má ṣe ilara ọmọnikeji wa.

Gal 5