1. NJẸ mo wipe, niwọn igbati arole na ba wà li ewe, kò yàtọ ninu ohunkohun si ẹrú bi o tilẹ jẹ oluwa ohun gbogbo;
2. Ṣugbọn o wà labẹ olutọju ati iriju titi fi di akokò ti baba ti yàn tẹlẹ.
3. Gẹgẹ bẹ̃ si li awa, nigbati awa wà li ewe, awa wà li ondè labẹ ipilẹṣẹ ẹda:
4. Ṣugbọn nigbati akokò kíkun na de, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ jade wá, ẹniti a bí ninu obinrin, ti a bi labẹ ofin,