Gal 2:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ṣugbọn kàkà bẹ̃, nigbati nwọn ri pe a ti fi ihinrere ti awọn alaikọla le mi lọwọ, bi a ti fi ihinrere ti awọn onila le Peteru lọwọ;

8. (Nitori ẹniti o ṣiṣẹ ninu Peteru si iṣẹ Aposteli ti ikọla, on kanna li o ṣiṣẹ ninu mi fun awọn Keferi pẹlu),

9. Ati nigbati Jakọbu, ati Kefa, ati Johanu, awọn ẹniti o dabi ọwọ̀n, woye ore-ọfẹ ti a fifun mi, nwọn si fi ọwọ́ ọtún ìdapọ fun emi ati Barnaba, pe ki awa ki o mã lọ sọdọ awọn Keferi, ati awọn sọdọ awọn onila.

10. Kìki nwọn fẹ ki a mã ranti awọn talakà, ohun kanna gan ti mo nfi titaratitara ṣe pẹlu.

11. Ṣugbọn nigbati Peteru wá si Antioku, mo ta kò o li oju ara rẹ̀, nitoriti o jẹ ẹniti a ba bawi.

Gal 2