19. Ṣugbọn emi kò ri ẹlomiran ninu awọn Aposteli miran, bikoṣe Jakọbu arakunrin Oluwa.
20. Nkan ti emi nkọ̀we si nyin yi, kiyesi i, niwaju Ọlọrun emi kò ṣeke.
21. Lẹhin na mo si wá si ẹkùn Siria ati ti Kilikia;
22. Mo sì jẹ ẹniti a kò mọ̀ li oju fun awọn ijọ ti o wà ninu Kristi ni Judea:
23. Ṣugbọn kìki nwọn ti gbọ́ pe, Ẹniti o ti nṣe inunibini si wa rí, si nwasu igbagbọ́ na nisisiyi, ti o ti mbajẹ nigbakan rí.
24. Nwọn si nyin Ọlọrun logo nitori mi.