Est 5:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nigbana ni ọba wi pe, ẹ mu ki Hamani ki o yara, ki on ki o le ṣe bi Esteri ti wi. Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá si àse na ti Esteri ti sè silẹ.

6. Ọba si wi fun Esteri nibiti nwọn gbe nmu ọti-waini pe, kini ibere rẹ? a o si fi fun ọ: ki si ni ẹ̀bẹ rẹ? ani de idajì ijọba, a o si ṣe e.

7. Nigbana ni Esteri dahùn, o si wi pe, ẹ̀bẹ mi ati ibère mi ni pe,

8. Bi mo ba ri ore-ọfẹ loju ọba, bi o ba si wù ọba lati fi ohun ti emi ntọrọ fun mi, ati lati ṣe ohun ti emi mbère fun mi, jẹ ki ọba ati Hamani ki o wá si àse ti emi o si tun sè fun wọn, emi o si ṣe li ọla bi ọba ti wi.

9. Nigbana ni Hamani jade lọ li ọjọ na tayọ̀tayọ̀, ati pẹlu inu didùn: ṣugbọn nigbati Hamani ri Mordekai li ẹnu ọ̀na ile ọba pe, kò dide duro, bẹ̃ni kò pa ara rẹ̀ da fun on, Hamani kún fun ibinu si Mordekai.

10. Ṣugbọn Hamani kó ara rẹ̀ ni ijanu: nigbati o si de ile, o ranṣẹ lọ ipè awọn ọrẹ rẹ̀, ati Sereṣi aya rẹ̀.

Est 5