17. Mo si rán wọn ti awọn ti aṣẹ si ọdọ Iddo, olori ni ibi Kasifia, mo si kọ́ wọn li ohun ti nwọn o wi fun Iddo, ati fun awọn arakunrin rẹ̀, awọn Netinimu ni ibi Kasifia, ki nwọn ki o mu awọn iranṣẹ wá si ọdọ wa fun ile Ọlọrun wa.
18. Ati nipa ọwọ rere Ọlọrun wa lara wa, nwọn mu ọkunrin oloye kan fun wa wá, ninu awọn ọmọ Mali, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli; ati Ṣerebiah, pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, mejidilogun.
19. Ati Haṣabiah, ati pẹlu rẹ̀ Jeṣaiah, ninu awọn ọmọ Merari, awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ wọn, ogún;
20. Ninu awọn Netinimu pẹlu, ti Dafidi ati awọn ijoye ti fi fun isin awọn ọmọ Lefi, ogunlugba Netinimu gbogbo wọn li a kọ orukọ wọn.