Li ọdun ikini Kirusi ọba, Kirusi ọba na paṣẹ nipasẹ ile Ọlọrun ni Jerusalemu pe, Ki a kọ́ ile na, ibi ti nwọn o ma ru ẹbọ, ki a si fi ipilẹ rẹ̀ lelẹ ṣinṣin, ki giga rẹ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ọgọta igbọnwọ.