21. Awọn ọmọ Israeli ti o ti inu igbekun pada bọ̀, ati gbogbo iru awọn ti o ti ya ara wọn si ọdọ wọn kuro ninu ẽri awọn keferi ilẹ na, lati ma ṣe afẹri Oluwa Ọlọrun Israeli, si jẹ àse irekọja.
22. Nwọn si fi ayọ̀ ṣe ajọ aiwukara li ọjọ meje: nitoriti Oluwa ti mu wọn yọ̀, nitoriti o yi ọkàn ọba Assiria pada si ọdọ wọn, lati mu ọwọ wọn le ninu iṣẹ ile Ọlọrun, Ọlọrun Israeli.