15. A si pari ile yi li ọjọ kẹta oṣu Adari, ti iṣe ọdun kẹfa ijọba Dariusi ọba.
16. Awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi pẹlu awọn ọmọ ìgbekun ìyoku ṣe ìyasimimọ́ ile Ọlọrun yi pẹlu ayọ̀.
17. Ni iyasimimọ́ ile Ọlọrun yi, ni nwọn si rubọ ọgọrun akọ-malu, igba àgbo, irinwo ọdọ-agutan; ati fun ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli, obukọ mejila gẹgẹ bi iye awọn ẹ̀ya Israeli: