10. Ki nwọn ki o le ru ẹbọ olõrun, didùn si Ọlọrun ọrun, ki nwọn ki o si le ma gbadura fun ẹmi ọba, ati ti awọn ọmọ rẹ̀.
11. Pẹlupẹlu mo ti paṣẹ pe, ẹnikẹni ti o ba yi ọ̀rọ yi pada, ki a fa igi lulẹ li ara ile rẹ̀, ki a si gbe e duro, ki a fi on na kọ si ori rẹ̀, ki a si sọ ile rẹ̀ di ãtàn nitori eyi.
12. Ki Ọlọrun ẹniti o mu ki orukọ rẹ̀ ma gbe ibẹ, ki o pa gbogbo ọba, ati orilẹ-ède run, ti yio da ọwọ wọn le lati ṣe ayipada, ati lati pa ile Ọlọrun yi run, ti o wà ni Jerusalemu. Emi Dariusi li o ti paṣẹ, ki a mu u ṣẹ li aijafara.
13. Nigbana ni Tatnai bãlẹ ni ihahin-odò, Ṣetarbosnai, ati awọn ẹgbẹ wọn, gẹgẹ bi eyiti Dariusi ọba ti ranṣẹ, bẹ̃ni nwọn ṣe li aijafara.
14. Awọn àgba Juda si kọle, nwọn si ṣe rere nipa iyanju Haggai woli ati Sekariah ọmọ Iddo. Nwọn si kọle, nwọn si pari rẹ̀ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Israeli, ati gẹgẹ bi aṣẹ Kirusi, ati Dariusi ati Artasasta ọba Persia.
15. A si pari ile yi li ọjọ kẹta oṣu Adari, ti iṣe ọdun kẹfa ijọba Dariusi ọba.