Esr 6:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Dariusi ọba paṣẹ, a si wá inu ile ti a ko iwe jọ si, nibiti a to iṣura jọ si ni Babiloni.

2. A si ri iwe kan ni Ekbatana, ninu ilu olodi ti o wà ni igberiko Medea, ati ninu rẹ̀ ni iwe-iranti kan wà ti a kọ bayi:

3. Li ọdun ikini Kirusi ọba, Kirusi ọba na paṣẹ nipasẹ ile Ọlọrun ni Jerusalemu pe, Ki a kọ́ ile na, ibi ti nwọn o ma ru ẹbọ, ki a si fi ipilẹ rẹ̀ lelẹ ṣinṣin, ki giga rẹ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ọgọta igbọnwọ.

4. Ilè okuta nla mẹta, ati ilè igi titun kan: ki a si ṣe inawo rẹ̀ lati inu ile ọba wa:

5. Pẹlupẹlu ki a si kó ohun èlo wura ati ti fàdaka ile Ọlọrun pada, ti Nebukadnessari ti kó lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si ti ko wá si Babiloni, ki a si ko wọn pada, ki a si mu wọn lọ si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, olukuluku ni ipò rẹ̀, ki a si tò wọn si inu ile Ọlọrun.

6. Njẹ nisisiyi Tatnai, bãlẹ oke-odò, Ṣetarbosnai, ati awọn ẹgbẹ nyin, awọn ara Afarsaki, ti o wà li oke-odò, ki ẹnyin ki o jina si ibẹ.

7. Ẹ jọwọ́ iṣẹ ile Ọlọrun yi lọwọ, ki balẹ awọn ara Juda, ati awọn àgba awọn ara Juda ki nwọn kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀.

Esr 6