1. O si fi ohùn rara kigbe li eti mi wipe, Mu gbogbo awọn alaṣẹ ilu sunmọ itosi, olukuluku ton ti ohun ija iparun li ọwọ́ rẹ̀.
2. Si kiyesi i, ọkunrin mẹfa jade lati ẹnu ilẹkun oke wá, ti o wà niha ariwa, olukuluku ton ti ohun-ijà ipani li ọwọ́ rẹ̀: ọkunrin kan ninu wọn si wọ aṣọ ọgbọ̀, pẹlu ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀: nwọn si wọ inu ile, nwọn si duro lẹba pẹpẹ idẹ.
3. Ogo Ọlọrun Israeli si ti goke kuro lori kerubu, eyi ti o ti wà, si iloro ile. O si pe ọkunrin na ti o wọ aṣọ ọgbọ̀, ti o ni ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀:
4. Oluwa si wi fun u pe, La ãrin ilu já, li ãrin Jerusalemu, ki o si sami si iwaju awọn ọkunrin ti nkẹdùn, ti nwọn si nkigbe nitori ohun irira ti nwọn nṣe lãrin rẹ̀.
5. O si sọ fun awọn iyokù li eti mi, pe, Ẹ tẹ̀ le e la ilu lọ, ẹ si ma kọlù: ẹ má jẹ ki oju nyin dasi, bẹ̃ni ẹ máṣe ṣãnu.
6. Ẹ pa arugbo ati ọmọde patapata, awọn wundia ati ọmọ kekeke ati obinrin; ṣugbọn ẹ máṣe sunmọ ẹnikan lara ẹniti àmi na wà; ẹ si bẹrẹ lati ibi mimọ́ mi. Bẹ̃ni nwọn bẹrẹ lati ọdọ awọn agbà ti o wà niwaju ile.