Esek 6:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, emi kò wi lasan pe, emi o ṣe ibi yi si wọn.

11. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; pàtẹwọ rẹ, si fi ẹsẹ rẹ kì ilẹ; si wipe, o ṣe! fun gbogbo irira buburu ilẹ Israeli, nitori nwọn o ṣubu nipa idà, nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ àrun.

12. Ẹniti o jina rere yio kú nipa ajakalẹ àrun; ati ẹniti o sunmọ tosí yio ṣubu nipa idà; ati ẹniti o kù ti a si do tì yio kú nipa iyàn: bayi li emi o mu irunu mi ṣẹ lori wọn.

13. Nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati okú wọn yio wà larin ere wọn yi pẹpẹ wọn ka, lori oke kekeke gbogbo, lori ṣonṣo ori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo, ati labẹ gbogbo igi oaku bibò, ibiti nwọn ti rubọ õrùn didùn si gbogbo ere wọn.

14. Bẹ̃ li emi o nà ọwọ́ mi jade sori wọn, emi o si sọ ilẹ na di ahoro, nitotọ, yio di ahoro jù aginju iha Diblati lọ, ninu gbogbo ibugbe wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esek 6