1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2. Ọmọ enia, kọju rẹ si awọn oke-nla Israeli, si sọtẹlẹ si wọn.
3. Si wipe, Ẹnyin oke-nla Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; bayi li Oluwa Ọlọrun wi si awọn oke-nla, si awọn oke kekeke, si awọn odò siṣàn, ati si awọn afonifoji; kiyesi i, Emi, ani Emi, o mu idà wá sori nyin, emi o si pa ibi giga nyin run.
4. Pẹpẹ nyin yio si di ahoro, ere nyin yio si fọ; okú nyin li emi o si gbe jù siwaju oriṣa nyin.