Esek 48:29-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Eyi ni ilẹ ti ẹnyin o fi ìbo pin ni ogún fun awọn ẹ̀ya Israeli, wọnyi si ni ipin wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.

30. Wọnyi si ni ibajade ti ilu-nla na lati ìha ariwa, ẹgbã-meji, o le ẹ̃dẹgbẹta oṣùwọn.

31. Awọn bode ilu-nla na yio jẹ gẹgẹ bi orukọ awọn ẹ̀ya Israeli: bodè mẹta nihà ariwa, bodè Reubeni ọkan, bodè Juda ọkan, bodè Lefi ọkan.

32. Ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta: ati bodè mẹta; ati bode Josefu ọkan, bode Benjamini ọkan, bodè Dani ọkan.

33. Ati ni ihà gusu, ẹgbã-meji, o le ẹ̃dẹgbẹta ìwọn: ati bodè mẹta; bodè Simeoni ọkan, bodè Issakari ọkan, bodè Sebuloni ọkan.

34. Ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, pẹlu bodè mẹta wọn; bodè Gadi ọkan, bodè Aṣeri ọkan, bodè Naftali ọkan.

35. O jẹ ẹgbã-mẹsan ìwọn yika: orukọ ilu-nla na lati ijọ na lọ yio ma jẹ, Oluwa mbẹ nibẹ̀.

Esek 48