8. O si wi fun mi pe, Omi wọnyi ntú jade sihà ilẹ ila-õrun, nwọn si nsọkalẹ lọ si pẹ̀tẹlẹ, nwọn si wọ̀ okun lọ: nigbati a si mu wọn wọ̀ inu okun, a si mu omi wọn lara dá.
9. Yio si ṣe pe, ohunkohun ti o ba wà lãye ti nrakò, nibikibi ti odò mejeji ba de, yio wà lãye: ọ̀pọlọpọ ẹja yio si de, nitori omi wọnyi yio de ibẹ̀: a o si mu wọn lara dá; ohun gbogbo yio si yè nibikibi ti odò na ba de.
10. Yio si ṣe pe, Awọn apẹja yio duro lori rẹ̀ lati Engedi titi de Eneglaimu; nwọn o jẹ ibi lati nà àwọn si; ẹja wọn o dabi iru wọn, bi ẹja okun-nla, lọpọlọpọ.
11. Ṣugbọn ibi ẹrẹ̀ rẹ̀ ati ibi irà rẹ̀ li a kì o mu laradá; a o fi nwọn fun iyọ̀.