1. BAYI li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹnu-ọ̀na agbala ti inu ti o kọju si ila-õrun yio wà ni titì ni ọjọ mẹfa ti a fi iṣiṣẹ; ṣugbọn ni ọjọ isimi li a o ṣi i silẹ, ati li ọjọ oṣù titun li a o si ṣi i silẹ.
2. Olori na yio si ba ẹnu-ọ̀na iloro ti ẹnu-ọ̀na ode wọle, yio si duro nibi opó ẹnu-ọ̀na, awọn alufa yio si pèse ọrẹ ẹbọ sisun rẹ̀ ati ọrẹ ẹbọ idupẹ rẹ̀, on o si ma sìn ni iloro ẹnu-ọ̀na: yio si jade wá; a kì yio si tì ẹnu-ọ̀na titi di aṣalẹ.
3. Enia ilẹ na yio si ma sìn ni ilẹkùn ẹnu-ọ̀na yi niwaju Oluwa ni ọjọ isimi, ati ni oṣù titun.
4. Ọrẹ-ẹbọ sisun ti olori na yio rú si Oluwa ni ọjọ isimi, yio jẹ ọdọ-agutan mẹfa alailabawọn, ati agbò kan alailabàwọn.
5. Ati ọrẹ ẹbọ jijẹ yio jẹ efà kan fun agbò kan, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.
6. Ati li ọjọ oṣù titun, ẹgbọ̀rọ malũ kan ailabawọn, ati ọdọ-agutan mẹfa, ati agbò kan: nwọn o wà lailabàwọn.
7. Yio si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ, efa fun ẹgbọ̀rọ akọ malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan gẹgẹ bi ọwọ́ rẹ̀ ba ti to, ati hini ororo kan fun efa kan.
8. Nigbati olori na yio ba si wọle, ọ̀na iloro ẹnu-ọ̀na ni yio ba wọle, yio si ba ọ̀na rẹ̀ jade.