1. PẸLUPẸLU nigbati ẹnyin ba fi ibo pín ilẹ li ogún, ẹ o gbé ọrẹ wá fun Oluwa, eyiti o mọ́ lati ilẹ na wá: gigùn na yio jẹ ẹgbã le ẹgbẹrun ije ni gigùn, ati ẹgbãrun ni ibú. Eyi yio jẹ́ mimọ́ ni gbogbo àgbegbe rẹ̀ yika.
2. Lati inu eyi, ẹ̃dẹgbẹta yio jẹ ti ibi-mimọ́ ni gigùn, pẹlu ẹ̃dẹgbẹta ni ibú, ni igun mẹrẹrin yika; ati adọta igbọnwọ fun igbangba rẹ̀ yika.
3. Ati ninu ìwọn yi ni iwọ o wọ̀n ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbarun ni ibú; ati ninu rẹ̀ ni ibi-mimọ́ yio wà, ibi-mimọ́ julọ.
4. Eyi ti o mọ́ ninu ilẹ na yio jẹ ti awọn alufa, awọn iranṣẹ ibi-mimọ́, ti yio sunmọ lati ṣe iránṣẹ fun Oluwa: yio si jẹ àye fun ile wọn, ati ibi-mimọ́ fun ibi-mimọ́.
5. Ati ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigun, ati ti ẹgbãrun ni ibú, ni awọn Lefi, pẹlu awọn iranṣẹ ile na, ni ogún yará, fun ara wọn, ni ini.
6. Ati ini ilu na li ẹnyin o yàn ẹgbarun ni ibú, ati ẹgba mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, lẹba ọrẹ ipín mimọ́ na: yio jẹ ti gbogbo ile Israeli.