6. Emi o si rán iná si Magogu, ati sãrin awọn ti ngbe erekuṣu laibẹ̀ru; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
7. Emi o si sọ orukọ mimọ́ mi di mimọ̀ lãrin enia mi Israeli; emi kì yio si jẹ ki nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ mọ: awọn orilẹ-ède yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ni Israeli.
8. Kiye si i, o ti de, a si ti ṣe e; ni Oluwa Ọlọrun wi, eyi ni ọjọ ti emi ti sọ.
9. Awọn ti o si ngbe ilu Israeli yio jade lọ, nwọn o si fi ohun ihamọra wọnni jona ati asa ati apata, ọrun ati ọfà, kùmọ ati ọ̀kọ; nwọn o si fi iná sun wọn li ọdun meje:
10. Nwọn kì yio lọ rù igi lati inu oko wá, bẹ̃ni nwọn kì yio ke igi lulẹ lati inu igbẹ́ wá; nitori ohun ihamọra ni nwọn ti fi daná; nwọn o si ko awọn ti o ko wọn, nwọn o si dọdẹ awọn ti o dọdẹ wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.
11. Yio si ṣe li ọjọ na, emi o fi ibikan fun Gogu nibẹ fun iboji ni Israeli, afonifoji awọn èro ni gabasi okun; on si pa awọn èro ni ẹnu mọ: nibẹ ni nwọn o gbe sin Gogu ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ si: nwọn o si pè e ni, Afonifoji Hamon-gogu.
12. Oṣù meje ni ile Israeli yio si ma fi sin okú wọn, ki nwọn ba le sọ ilẹ na di mimọ́.