10. Bẹ̃ni mo sọtẹlẹ gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun mi, ẽmi na si wá sinu wọn, nwọn si yè, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn ogun nlanla.
11. Nigbana li o sọ fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi ni gbogbo ile Israeli: wò o, nwọn wipe, Egungun wa gbẹ, ireti wa si pin: ni ti awa, a ti ke wa kuro.
12. Nitorina sọtẹlẹ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, ẹnyin enia mi, emi o ṣi ibojì nyin, emi o si mu ki ẹ dide kuro ninu ibojì nyin, emi o si mu nyin wá si ilẹ Israeli.
13. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi bá ti ṣí ibojì nyin, ẹnyin enia mi, ti emi bá si mu nyin dide kuro ninu ibojì nyin.
14. Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, ẹnyin o si yè, emi o si mu nyin joko ni ilẹ ti nyin: nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ ọ, ti o si ti ṣe e, li Oluwa wi.
15. Ọrọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
16. Ati iwọ, ọmọ enia, mu igi kan, si kọwe si i lara, Fun Juda, ati fun awọn ọmọ Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀: si mu igi miran, si kọwe si i lara, Fun Josefu, igi Efraimu, ati fun gbogbo ile Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀.
17. Si dà wọn pọ̀ ṣọkan si igi kan; nwọn o si di ọkan li ọwọ́ rẹ.
18. Nigbati awọn enia rẹ ba ba ọ sọ̀rọ, wipe, Iwọ kì yio fi idi nkan wọnyi hàn wa?
19. Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu igi Josefu, ti o wà li ọwọ́ Efraimu, ati awọn ẹya Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀, emi o si mu wọn pẹlu rẹ̀, pẹlu igi Juda, emi o si sọ wọn di igi kan, nwọn o si di ọkan li ọwọ́ mi.
20. Igi ti iwọ kọwe si lara yio wà li ọwọ́ rẹ, niwaju wọn.
21. Si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu awọn ọmọ Israeli kuro lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ, emi o si ṣà wọn jọ niha gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ti wọn.