37. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli yio bere eyi lọwọ mi, lati ṣe e fun wọn, emi o mu enia bi si i fun wọn bi ọwọ́-ẹran.
38. Gẹgẹ bi ọwọ́-ẹran mimọ́, bi ọwọ́-ẹran Jerusalemu ni àse wọn ti o ni ironu, bẹ̃ni ilu ti o di ahoro yio kún fun enia: nwọn o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.