Esek 36:21-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ṣugbọn ãnu orukọ mimọ́ mi ṣe mi, ti ile Israeli ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ.

22. Nitorina sọ fun ile Israeli, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli, emi kò ṣe eyi nitori ti nyin, ṣugbọn fun orukọ mimọ́ mi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti ẹnyin lọ.

23. Emi o si sọ orukọ nla mi di mimọ́, ti a bajẹ lãrin awọn keferi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin wọn; awọn keferi yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati a o sọ mi di mimọ́ ninu nyin niwaju wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.

24. Nitori emi o mu nyin kuro lãrin awọn keferi, emi o si ṣà nyin jọ kuro ni gbogbo ilẹ, emi o si mu nyin padà si ilẹ ti nyin.

25. Nigbana ni emi o fi omi mimọ́ wọ́n nyin, ẹnyin o si mọ́: emi o si wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin.

Esek 36