Esek 32:16-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Eyi ni ohùn-rére, nwọn o si pohùnrére rẹ̀: awọn ọmọbinrin awọn orilẹ-ède yio pohùnrére rẹ̀: nwọn o pohùnrére nitori rẹ̀, ani fun Egipti, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.

17. O si tun ṣe li ọdun kejila, li ọjọ kẹ̃dogun oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe.

18. Ọmọ enia, pohùnrére fun ọ̀pọlọpọ enia Egipti, ki o si sọ̀ wọn kalẹ, on, ati awọn ọmọbinrin orilẹ-ède olokiki, si ìsalẹ aiye, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ sinu ihò.

19. Tani iwọ julọ li ẹwà? sọkalẹ, ki a si tẹ́ ọ tì awọn alaikọla.

20. Nwọn o ṣubu li ãrin awọn ti a fi idà pa: a fi on le idà lọwọ: fà a, ati awọn ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀.

21. Awọn alagbara lãrin awọn alagbara yio sọ̀rọ si i lati ãrin ipò-okú wá, pẹlu awọn ti o ràn a lọwọ: nwọn sọkalẹ lọ, nwọn dubulẹ, awọn alaikọla ti a fi idà pa.

22. Assuru wà nibẹ̀ ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ wà lọdọ rẹ̀: gbogbo wọn li a pa, ti o ti ipa idà ṣubu:

23. Ibojì awọn ẹniti a gbe kà ẹgbẹ́ ihò, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ si yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti o da ẹ̀ru silẹ ni ilẹ alãye.

Esek 32