Esek 27:16-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Siria li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ iṣẹ ọwọ́ rẹ: nwọn ntà emeraldi li ọjà rẹ, pẹlu purpili, ati iṣẹ oniṣẹ-ọnà, ati ọ̀gbọ daradara, ati iyùn, ati agate.

17. Juda, ati ilẹ Israeli, awọn li awọn oniṣòwo rẹ, alikama ti Minniti, ati Pannagi, ati oyin, ati ororo, ati balmu, ni nwọn fi ná ọjà rẹ.

18. Damasku li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ ohun ọjà ti o ṣe, nitori ọ̀pọlọpọ ọrọ̀; ni ọti-waini ti Helboni, ati irun agutan funfun.

19. Dani pẹlu ati Jafani lati Usali ngbé ọjà rẹ: irin didán, kassia, ati kalamu wà li ọjà rẹ.

20. Dedani ni oniṣòwo rẹ ni aṣọ ibori fun kẹkẹ́.

21. Arabia, ati gbogbo awọn ọmọ-alade Kedari, awọn ni awọn oniṣòwo rẹ, ni ọdọ-agutan, ati agbò, ati ewurẹ; ninu wọnyi ni nwọn ṣe oniṣòwo rẹ.

22. Awọn oniṣòwo Ṣeba ati Rama, awọn li awọn oniṣòwo rẹ: nwọn tà onirũru turari daradara li ọjà rẹ, ati pẹlu onirũru okuta oniyebiye, ati wura.

23. Harani, ati Kanneh, ati Edeni, awọn oniṣòwo Ṣeba, Assuru, ati Kilmadi, ni awọn oniṣòwo rẹ.

24. Wọnyi li awọn oniṣòwo rẹ li onirũru nkan, ni aṣọ alaro, ati oniṣẹ-ọnà, ati apoti aṣọ oniyebiye, ti a fi okùn dì, ti a si fi igi kedari ṣe, ninu awọn oniṣòwo rẹ.

25. Awọn ọkọ Tarṣiṣi ni èro li ọjà rẹ: a ti mu ọ rẹ̀ si i, a si ti ṣe ọ logo li ãrin okun.

26. Awọn atukọ̀ rẹ ti mu ọ wá sinu omi nla: ẹfũfu ilà-õrun ti fọ́ ọ li ãrin okun.

27. Ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹ, ọjà tità rẹ, awọn atukọ̀ rẹ, ati atọ́kọ̀ rẹ, adikọ̀ rẹ, ati awọn alábarà rẹ, ati gbogbo awọn ologun rẹ, ti o wà ninu rẹ, ati ninu gbogbo ẹgbẹ́ rẹ, ti o wà li ãrin rẹ, yio ṣubu li ãrin okun li ọjọ iparun rẹ.

28. Awọn ilẹ àgbègbe yio mì nitori iró igbe awọn atọkọ̀ rẹ.

29. Gbogbo awọn alajẹ̀, awọn atukọ̀, ati awọn atọ́kọ̀ okun yio sọkalẹ kuro ninu ọkọ̀ wọn, nwọn o duro lori ilẹ.

30. Nwọn o si jẹ ki a gbọ́ ohùn wọn si ọ, nwọn o si kigbe kikoro, nwọn o si kù ekuru sori ara wọn, nwọn o si yi ara wọn ninu ẽru:

31. Nwọn o si fari wọn patapata fun ọ, nwọn o si fi aṣọ-àpo di ara wọn, nwọn o si sọkun fun ọ ni ikorò aiya, pẹlu ohùnrére ẹkun kikorò.

Esek 27