36. Oluwa tun sọ fun mi pe; Ọmọ enia, iwọ o ha dá Ahola ati Aholiba lẹ́jọ? nitõtọ sọ irira wọn fun wọn;
37. Pe, nwọn ti ṣe panṣaga ẹ̀jẹ si mbẹ lọwọ wọn, ati nipasẹ oriṣa wọn ni nwọn ti ṣe panṣaga, nwọn si ti jẹ ki awọn ọmọ wọn, ti nwọn bi fun mi, kọja lãrin iná fun wọn, lati run wọn.
38. Eyi ni nwọn si ṣe si mi; nwọn ti bà ibi mimọ́ mi jẹ li ọjọ kanna, nwọn sọ ọjọ isimi mi di aìlọwọ.
39. Nitoripe igbati nwọn pa awọn ọmọ wọn fun oriṣa wọn, nigbana ni nwọn wá ni ijọ kanna si ibi mimọ́ mi, lati sọ ọ di àilọwọ; si kiye si i, bayi ni nwọn ṣe lãrin ile mi.
40. Ati pẹlupẹlu, ti pe ẹnyin ranṣẹ pè awọn ọkunrin lati okẽre wá, sọdọ awọn ti a ranṣẹ pè; si kiyesi i, nwọn de: fun ẹniti iwọ wẹ̀ ara rẹ, ti o si le tirõ, ti o si fi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ li ọṣọ́.
41. Ti o si joko lori àkete daradara, a si tẹ́ tabili siwaju rẹ̀, lori eyi ti iwọ gbe turari mi ati ororó mi lé.