Esek 22:5-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Awọn ti o sunmọ tosí, ati awọn ti o jìna si ọ, yio fi ọ ṣẹ̀sin, iwọ ti a bà orukọ rẹ̀ jẹ, ti a si bà ninu jẹ pupọ.

6. Kiyesi i, awọn ọmọ-alade Israeli, olukuluku ninu agbara rẹ̀ wà ninu rẹ lati ta ẹjẹ silẹ.

7. Ninu rẹ ni nwọn kò ka baba ati iyá si: lãrin rẹ ni nwọn ti ni awọn alejo lara: ninu rẹ ni nwọn ti bà alaini-baba ati opo ninu jẹ.

8. Iwọ ti gan awọn ohun mimọ́ mi, o si ti sọ ọjọ isimi mi di ailọ̀wọ.

9. Ninu rẹ ni awọn ọkunrin ti o nṣe ofófo lati ta ẹjẹ silẹ wà: ninu rẹ ni nwọn si jẹun lori awọn oke: lãrin rẹ ni nwọn huwà ifẹkufẹ.

10. Ninu rẹ ni nwọn ti tu ihòho baba wọn: ninu rẹ ni nwọn ti tẹ́ obinrin ti a yà sapakan nitori aimọ́ rẹ̀ logo.

11. Ẹnikan si ti ṣe ohun irira pẹlu aya aladugbo rẹ̀: ẹlomiran si ti fi ifẹkufẹ bà aya-ọmọ rẹ̀ jẹ́; ẹlomiran ninu rẹ si ti tẹ́ arabinrin rẹ̀ logo, ọmọ baba rẹ̀.

12. Ninu rẹ ni nwọn ti gba ẹbùn lati ta ẹjẹ silẹ: iwọ ti gba ẹdá ati elé, o si ti fi iwọra jère lara awọn aladugbo rẹ, nipa ilọni lọwọ-gbà; o si ti gbagbe mi, ni Oluwa, Ọlọrun wi.

13. Kiyesi i, nitorina, mo ti fi ọwọ́ lu ọwọ̀ pọ̀ si ère aiṣõtọ rẹ ti o ti jẹ, ati si ẹjẹ rẹ ti o ti wà lãrin rẹ.

14. Ọkàn rẹ le gbà a, tabi ọwọ́ rẹ lè le, li ọjọ ti emi o ba ọ ṣe? emi Oluwa li o ti sọ ọ, emi o sì ṣe e.

15. Emi o fọ́n ọ ká sãrin awọn keferi, emi o si tú ọ ká si orilẹ-ède gbogbo, emi o si run ẽri rẹ kuro lara rẹ.

16. A o si sọ ọ di aìlọwọ ninu ara rẹ loju awọn keferi, iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

17. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

18. Ọmọ enia, ile Israeli di idarọ si mi: gbogbo wọn jẹ idẹ, ati tánganran, ati irin, ati ojé, lãrin ileru; ani nwọn jẹ idarọ fadaka.

19. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti gbogbo nyin di idarọ, kiyesi i, nitorina emi o ko nyin jọ si ãrin Jerusalemu.

20. Gẹgẹ bi nwọn ti ima ko fadaka, ati idẹ, ati irin, ati ojé, ati tánganran jọ si ãrin ileru, lati fin iná si i, ki a lè yọ́ ọ, bẹ̃ni emi o kó nyin ni ibinu mi, ati irúnu mi, emi o si fi nyin sibẹ emi o yọ́ nyin.

Esek 22