1. O si ṣe ni ọdun keje ni oṣu karun, ni ọjọ kẹwa oṣu, ti awọn kan ninu awọn àgba Israeli wá ibere lọwọ Oluwa, nwọn si joko niwaju mi.
2. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
3. Ọmọ enia, sọ fun awọn àgba Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Lati bere lọwọ mi ni ẹ ṣe wá? Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere.