24. Ṣugbọn nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedede, ti o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo irira ti enia buburu nṣe, on o ha yè? gbogbo ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni a kì yio ranti: ninu irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ninu wọn ni yio kú.
25. Ṣugbọn ẹnyin wipe, ọ̀na Oluwa kò gún. Gbọ́ nisisiyi, iwọ ile Israeli; ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún?
26. Nigbati olododo kan ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedẽde, ti o si kú ninu wọn; nitori aiṣedẽde rẹ̀ ti o ti ṣe ni yio kú.
27. Ẹwẹ, nigbati enia buburu ba yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si ṣe eyiti o tọ́, ati eyiti o yẹ, on o gba ọkàn rẹ̀ là lãye.
28. Nitoripe o bẹ̀ru o si yipada kuro ninu gbogbo irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, yiyè ni yio yè, on kì yio kú.
29. Ṣugbọn ile Israeli wipe, Ọ̀na Oluwa kò gún. Ile Israeli, ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún?