7. Idì nla miran si wà pẹlu apá nla ati iyẹ́ pupọ: si kiye si i, àjara yi tẹ̀ gbòngbo rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si yọ ẹka rẹ̀ sọdọ rẹ̀, ki o le ma b'omi si i ninu aporo ọgbà rẹ̀.
8. Ilẹ rere lẹba omi nla ni a gbìn i si, ki o le bà yọ ẹka jade, ki o si le so eso, ki o le jẹ́ àjara rere.
9. Wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; yio ha gbà? on kì yio hú gbòngbo rẹ̀, kì yio si ka eso rẹ̀ kuro, ki o le rọ? yio rọ ninu gbogbo ewe rirú rẹ̀, ani laisi agbara nla tabi enia pupọ̀ lati fà a tu pẹlu gbòngbo rẹ̀.
10. Nitõtọ, kiye si i, bi a ti gbìn i yi, yio ha gbà? kì yio ha rẹ̀ patapata? nigbati afẹfẹ ilà-õrun ba kàn a? yio rẹ̀ ninu aporo ti o ti hù.