10. Nitori, ani nitori ti nwọn ti tàn awọn enia mi wipe, Alafia; bẹ̃ni kò si alafia, ọkan si mọ ogiri, si kiyesi, awọn miran si nfi amọ̀ ti a kò pò rẹ́ ẹ.
11. Wi fun awọn ti nfi amọ̀ aipò rẹ́ ẹ, pe, yio ṣubu; òjo yio rọ̀ pupọ; ati Ẹnyin, yinyín nla, o si bọ́; ẹfũfu lile yio si ya a.
12. Kiyesi i, nigbati ogiri na ba wo, a kì yio ha wi fun nyin pe, Rirẹ́ ti ẹnyin rẹ́ ẹ ha dà?
13. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o tilẹ fi ẹfũfu lile ya a ni irúnu mi; òjo yio si rọ̀ pupọ ni ibinu mi, ati yinyin nla ni irúnu mi lati run u.
14. Bẹ̃ni emi o wo ogiri ti ẹnyin fi amọ̀ aipò rẹ́ lulẹ, emi o si mu u wá ilẹ, tobẹ̃ ti ipilẹ rẹ̀ yio hàn, yio si ṣubu, a o si run nyin li ãrin rẹ̀: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
15. Bayi li emi o mu ibinu mi ṣẹ lori ogiri na, ati lori awọn ti o fi amọ̀ aipò rẹ ẹ, emi o si wi fun nyin pe, Ogiri na kò si mọ ati awọn ti o ti rẹ́ ẹ;
16. Eyini ni, awọn woli Israeli, ti nwọn sọtẹlẹ niti Jerusalemu, ti nwọn si ri iran alafia fun u, bẹ̃ni alafia kò si, ni Oluwa Ọlọrun wi.