17. Ati ihò-ìtẹbọ fun opó wọnni jẹ́ idẹ; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà; ati ibori ori wọn jẹ́ fadakà; ati gbogbo opó agbalá na li a fi fadakà gbà li ọjá.
18. Ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na jẹ́ iṣẹ abẹ́rẹ, aṣọ-alaró, ati elesè-aluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ: ogún igbọnwọ si ni gigùn rẹ̀, ati giga ni ibò rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun, o bá aṣọ-tita agbalá wọnni ṣedede.
19. Opó wọn si jẹ́ mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ, mẹrin; kọkọrọ wọn jẹ́ fadakà, ati ibori ori wọn ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
20. Ati gbogbo ekàn agọ́ na, ati ti agbalá rẹ̀ yiká jẹ́ idẹ.
21. Eyi ni iye agọ́ na, agọ́ ẹrí nì, bi a ti kà wọn, gẹgẹ bi ofin Mose, fun ìrin awọn ọmọ Lefi, lati ọwọ́ Itamari wá, ọmọ Aaroni alufa.
22. Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, si ṣe ohun gbogbo ti OLUWA paṣẹ fun Mose.
23. Ati Oholiabu pẹlu rẹ̀, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, alagbẹdẹ, ati ọlọgbọ́n ọlọnà, alaró ati ahunṣọ alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara.