Eks 37:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, gẹgẹ bi ẹka mẹfẹfa ti o jade lara rẹ̀.

22. Irudi wọn ati ẹka wọn jẹ bakanna: gbogbo rẹ̀ jẹ́ iṣẹ lilù kìki wurà kan.

23. O si ṣe fitila rẹ̀, meje, ati alumagaji rẹ̀, ati awo rẹ̀, kìki wurà ni.

24. Talenti kan kìki wurà li o fi ṣe e, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀.

25. O si fi igi ṣittimu ṣe pẹpẹ turari: gigùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, ibú rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ kan, ìha mẹrin ọgbọgba; giga rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ meji; iwo rẹ̀ wà lara rẹ̀.

26. O si fi kìki wurà bò o, ati òke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀: o si ṣe igbáti wurà si i yiká.

27. O si ṣe oruka wurà meji si i nisalẹ̀ igbáti rẹ̀ na, ni ìha igun rẹ̀ meji, ìha mejeji rẹ̀, lati ṣe àye fun ọpá wọnni lati ma fi rù u.

28. O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn.

29. O si ṣe oróro mimọ́ itasori nì, ati õrùn didùn kìki turari, gẹgẹ bi iṣẹ alapòlu.

Eks 37