Eks 36:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BESALELI ati Oholiabu yio si ṣiṣẹ, ati olukuluku ọlọgbọ́n inu, ninu ẹniti OLUWA fi ọgbọn ati oyé si, lati mọ̀ bi a ti ṣiṣẹ onirũru iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA ti palaṣẹ.

2. Mose si pè Besaleli ati Oholiabu, ati gbogbo ọkunrin ọlọgbọ́n inu, ninu ọkàn ẹniti OLUWA fi ọgbọ́n si, ani gbogbo ẹniti inu wọn ru soke lati wá si ibi iṣẹ na lati ṣe e:

3. Nwọn si gbà gbogbo ọrẹ na lọwọ Mose, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, lati fi ṣe e. Sibẹ̀ nwọn si nmú ọrẹ ọfẹ fun u wá li orowurọ̀.

Eks 36