8. Ati oróro fun fitila, ati olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn;
9. Ati okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya.
10. Gbogbo ọlọgbọ́n inú ninu nyin yio si wá, yio si wá ṣiṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ;
11. Ibugbé na, ti on ti agọ́ rẹ̀, ati ibori rẹ̀, kọkọrọ rẹ̀, ati apáko rẹ̀, ọpá rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀;
12. Apoti nì, ati ọpá rẹ̀, itẹ́-ãnu nì, ati aṣọ-ikele na;
13. Tabili na, ati ọpá rẹ̀, ati ohun-èlo rẹ̀ gbogbo, ati àkara ifihàn nì;
14. Ati ọpà-fitila na fun titanna, ati ohun-elo rẹ̀, ati fitila rẹ̀, pẹlu oróro fun titanna.