11. Mose si wi fun Ọlọrun pe, Tali emi, ti emi o fi tọ̀ Farao lọ, ati ti emi o fi le mú awọn ọmọ Israeli jade lati Egipti wá?
12. O si wipe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ; eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ pe, emi li o rán ọ: nigbati iwọ ba mú awọn enia na lati Egipti jade wá, ẹnyin o sìn Ọlọrun lori oke yi.
13. Mose si wi fun Ọlọrun pe, Kiyesi i, nigbati mo ba dé ọdọ awọn ọmọ Israeli, ti emi o si wi fun wọn pe, Ọlọrun awọn baba nyin li o rán mi si nyin; ti nwọn o si bi mi pe, Orukọ rẹ̀? kili emi o wi fun wọn?
14. Ọlọrun si wi fun Mose pe, EMI NI ẸNITI O WA: o si wipe, Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, EMI NI li o rán mi si nyin.
15. Ọlọrun si wi fun Mose pẹlu pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o rán mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati irandiran.