Eks 28:20-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, ati oniki, ati jasperi: a o si tò wọn si oju wurà ni didè wọn.

21. Okuta wọnni yio si wà gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn; bi ifin edidi-àmi; olukuluku gẹgẹ bi orukọ rẹ̀ ni nwọn o wà fun ẹ̀ya Israeli mejejila.

22. Iwọ o si ṣe okùn ẹ̀wọn kìka wurà iṣẹ ọnà-lilọ si igbàiya na.

23. Iwọ o si ṣe oruka wurà meji sara igbàiya na, iwọ o si fi oruka meji na si eti mejeji igbàiya na.

24. Iwọ o si fi okùn ẹ̀wọn wurà mejeji sinu oruka meji wọnni li eti igbàiya na.

25. Ati eti ẹ̀wọn meji ni ki iwọ ki o so mọ́ oju-ìde mejeji, ki o si fi si ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀.

26. Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si eti mejeji igbàiya na li eti rẹ̀, ti o wà ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inú.

27. Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi mejeji nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ti o kọjusi isolù rẹ̀, loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na.

28. Nwọn o si fi oruka rẹ̀ so igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi na ti on ti ọjá àwọn alaró, ki o le wà loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ki a má si ṣe tú igbàiya na kuro lara ẹ̀wu-efodi na.

29. Aaroni yio si ma rù orukọ awọn ọmọ Israeli ninu igbàiya idajọ li àiya rẹ̀, nigbati o ba nwọ̀ ibi mimọ́ nì lọ, fun iranti nigbagbogbo niwaju OLUWA.

Eks 28