12. Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣe iṣẹ rẹ, ni ijọ́ keje ki iwọ ki o si simi: ki akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ ki o le simi, ki a le tù ọmọ iranṣẹbinrin rẹ, ati alejò, lara.
13. Ati li ohun gbogbo ti mo wi fun nyin, ẹ ma ṣọra: ki ẹ má si ṣe iranti orukọ oriṣakoriṣa ki a má ṣe gbọ́ ọ li ẹnu nyin.
14. Ni ìgba mẹta ni iwọ o ṣe ajọ fun mi li ọdún.
15. Iwọ o kiyesi ajọ aiwukàra: ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, bi mo ti pa a laṣẹ fun ọ, li akokò oṣù Abibu (nitori ninu rẹ̀ ni iwọ jade kuro ni Egipti); a kò gbọdọ ri ẹnikan niwaju mi li ọwọ́ ofo:
16. Ati ajọ ikore, akọ́so iṣẹ rẹ, ti iwọ gbìn li oko rẹ: ati ajọ ikore oko, li opin ọdún, nigbati iwọ ba ṣe ikore iṣẹ oko rẹ tán.
17. Ni ìgba mẹta li ọdún ni gbogbo awọn ọkunrin rẹ yio farahàn niwaju Oluwa JEHOFA.