6. Nigbana ni ki oluwa rẹ̀ ki o mú u lọ sọdọ awọn onidajọ; yio si mú u lọ si ẹnu-ọ̀na, tabi si opó ẹnu-ọ̀na; oluwa rẹ̀ yio si fi olù lú u li eti; on a si ma sìn i titi aiye.
7. Bi ẹnikan ba si tà ọmọ rẹ̀ obinrin li ẹrú, on ki yio jade lọ bi awọn ẹrú ọkunrin ti ijade lọ.
8. Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ.
9. Bi o ba si fẹ́ ẹ fun ọmọkunrin rẹ̀, ki o ma ṣe si i bi a ti iṣe si ọmọbinrin ẹni.
10. Bi o ba si fẹ́ obinrin miran; onjẹ rẹ̀, aṣọ rẹ̀, ati iṣe ọkọlaya rẹ̀, ki o máṣe yẹ̀.
11. Bi on ki yio ba si ṣe ohun mẹtẹta yi fun u, njẹ ki on ki o jade kuro lọfẹ li aisan owo.
12. Ẹniti o ba lù enia, tobẹ̃ ti o si ku, pipa li a o pa a.
13. Bi o ba ṣepe enia kò ba dèna, ṣugbọn ti o ṣepe Ọlọrun li o fi lé e lọwọ, njẹ emi o yàn ibi fun ọ, nibiti on o gbé salọ si.
14. Ṣugbọn bi enia ba ṣìka si aladugbo rẹ̀, lati fi ẹ̀tan pa a; ki iwọ ki o tilẹ mú u lati ibi pẹpẹ mi lọ, ki o le kú.
15. Ẹniti o ba si lù baba, tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a.
16. Ẹniti o ba si ji enia, ti o si tà a, tabi ti a ri i li ọwọ́ rẹ̀, pipa li a o pa a.
17. Ẹniti o ba si bú baba tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a.
18. Bi awọn ọkunrin ba si jùmọ̀ njà, ti ekini fi okuta lù ekeji, tabi ti o jìn i li ẹsẹ̀, ti on kò si kú ṣugbọn ti o da a bulẹ:
19. Bi o ba si tun dide, ti o ntẹ̀ ọpá rìn kiri ni ita, nigbana li ẹniti o lù u yio to bọ́; kìki gbèse akokò ti o sọnù ni yio san, on o si ṣe ati mu u lara da ṣaṣa.
20. Bi ẹnikan ba si fi ọpá lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin, ti o si kú si i li ọwọ́, a o gbẹsan rẹ̀ nitõtọ.
21. Ṣugbọn bi o ba duro di ijọ́ kan, tabi meji, a ki yio gbẹsan rẹ̀: nitoripe owo rẹ̀ ni iṣe.
22. Bi awọn ọkunrin ba njà, ti nwọn si pa obinrin aboyún lara, tobẹ̃ ti oyún rẹ̀ ṣẹ́, ṣugbọn ti ibi miran kò si pẹlu: a o mu ki o san nitõtọ, gẹgẹ bi ọkọ obinrin na yio ti dá lé e; on o si san a niwaju onidajọ.