2. Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni ni ijù na:
3. Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi.
4. Nigbana li OLUWA sọ fun Mose pe, Kiyesi i, emi o rọ̀jo onjẹ fun nyin lati ọrun wá; awọn enia yio si ma jade lọ ikó ìwọn ti õjọ li ojojumọ́, ki emi ki o le dan wọn wò, bi nwọn o fẹ́ lati ma rìn nipa ofin mi, bi bẹ̃kọ.
5. Yio si ṣe, li ọjọ́ kẹfa, nwọn o si pèse eyiti nwọn múwa; yio si to ìwọn meji eyiti nwọn ima kó li ojojumọ́.
6. Mose ati Aaroni si wi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli pe, Li aṣalẹ, li ẹnyin o si mọ̀ pe, OLUWA li o mú nyin jade lati Egipti wá:
7. Ati li owurọ̀ li ẹnyin o si ri ogo OLUWA; nitoriti o gbọ́ kikùn nyin si OLUWA: ta si li awa, ti ẹnyin nkùn si wa?
8. Mose si wi pe, Bayi ni yio ri nigbati OLUWA yio fun nyin li ẹran jẹ li aṣalẹ, ati onjẹ ajẹyo li owurọ̀; nitoriti OLUWA gbọ́ kikùn nyin ti ẹnyin kùn si i: ta si li awa? kikùn nyin ki iṣe si wa, bikoṣe si OLUWA.