Ṣugbọn awọn ara Egipti lepa wọn, gbogbo ẹṣin ati kẹkẹ́ Farao, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, ati awọn ogun rẹ̀, o si lé wọn bá, nwọn duro li ẹba okun ni ìha Pi-hahirotu niwaju Baal-sefoni.