28. Omi si pada, o si bò kẹkẹ́, ati awọn ẹlẹṣin, ati gbogbo ogun Farao ti o wọ̀ inu okun tọ̀ wọn lẹhin lọ; ọkanṣoṣo kò kù ninu wọn.
29. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli rìn ni iyangbẹ ilẹ lãrin okun; omi si jẹ́ odi fun wọn li ọwọ́ ọtún, ati li ọwọ́ òsi wọn.
30. Bayi li OLUWA gbà Israeli là li ọjọ́ na lọwọ awọn ara Egipti; Israeli si ri okú awọn ara Egipti leti okun.
31. Israeli si ri iṣẹ nla ti OLUWA ṣe lara awọn ara Egipti: awọn enia na si bẹ̀ru OLUWA, nwọn si gbà OLUWA ati Mose iranṣẹ rẹ̀ gbọ́.