Eks 14:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nigbati Farao si nsunmọtosi, awọn ọmọ Israeli gbé oju soke, si kiyesi i, awọn ara Egipti mbọ̀ lẹhin wọn; ẹ̀ru si bà wọn gidigidi: awọn ọmọ Israeli si kigbe pè OLUWA.

11. Nwọn si wi fun Mose pe, Nitoriti isà kò sí ni Egipti, ki iwọ ṣe mú wa wá lati kú ni ijù? ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃, lati mú wa jade ti Egipti wá?

12. Ọrọ yi ki awa ti sọ fun ọ ni Egipti pe, Jọwọ wa jẹ ki awa ki o ma sìn awọn ara Egipti? O sá san fun wa lati ma sin awọn ara Egipti, jù ki awa kú li aginjù lọ.

13. Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri ìgbala OLUWA, ti yio fihàn nyin li oni: nitori awọn ara Egipti ti ẹnyin ri li oni yi, ẹnyin ki yio si tun ri wọn mọ́ lailai.

14. Nitoriti OLUWA yio jà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pa ẹnu nyin mọ́.

Eks 14