20. Nwọn si mu ọ̀na-àjo wọn pọ̀n lati Sukkoti lọ, nwọn si dó si Etamu leti ijù.
21. OLUWA si nlọ niwaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma li ọsán, lati ma ṣe amọna fun wọn; ati li oru li ọwọ̀n iná lati ma fi imọlẹ fun wọn; lati ma rìn li ọsán ati li oru.
22. Ọwọ̀n awọsanma na kò kuro li ọsán, tabi ọwọ̀n iná li oru, niwaju awọn enia na.