20. A si ngbé nyin ró lori ipilẹ awọn aposteli, ati awọn woli, Jesu Kristi tikararẹ̀ jẹ pàtaki okuta igun ile;
21. Ninu ẹniti gbogbo ile na, ti a nkọ ṣọkan pọ, ndagbà soke ni tẹmpili mimọ́ ninu Oluwa:
22. Ninu ẹniti a ngbé nyin ró pọ pẹlu fun ibujoko Ọlọrun ninu Ẹmí.